Ile ẹjọ ti fun Olisa Metuh ni beeli ẹgbẹ̀ta millionu naira

image

Ile ẹjọ kan ni olu ilu Abuja ni ọjọ ẹti, ti
fun akọwe agba ẹgbẹ PDP, Olisa Metuh, ni beeli ti apaọ rẹ jẹ ẹgbẹ̀ta millionu (600 million) naira pẹlu oluduro meji.

Ọgbẹni Metuh ti wa ni atimọle labẹ aṣẹ ile ẹjọ miran nipa ẹsun irinwó millionu (400 million) naira ti o ko jẹ, lati ari owo ti ijọba ya sọtọ fun rira nkan ijagun fun awọn jagun jagun, ti o gba lọwọ onimọran fun ijọba lori ọrọ idaabobo ilu tẹlẹ, Ọgbẹni Sambo Dasuki ni oṣu kọkanla ọdun 2014.

Leave a comment